Awon agbebon kan ti yin ibon pa omo egbe ile igbimo asofin Olatoye Temitope ‘Sugar’ ninu eto idibo to waye ni ipinle Oyo

Ninu eto idibo to waye ni ipinle Oyo lana ni awon agbebon kan ti yi ibon pa ogbeni Olatoye Temitope eni ti gbogbo eyan mo si sugar ni agbegbe  Elesu ni Ward 13, ijoba ipinle Lalupon, Lagelu ni ipinle Oyo. 

Ologbe Temitope Sugar eni to je ikan ninu awon omo egbe ile igbimo asofin ton soju ekun Lagelu ati Akinyele ni ipinle Oyo labe egbe oloselu APC ni awon janduku da emi re legbodo ni osan ana.

Iwadi to peye ti bere lori oro na, awon agbofinro si ti pinu lati mu gbogbo awon to lowo si isele na.

Agbenuso ile igbimo asofin ogbeni Yakubu Dogara ti fi idi isele na mule ninu atejade kan to se lori ero ayelujara re to si kedun pelu awon molebi ologbe na.

Atejade na ni yi ni ede geesi;

 'I received with shock, the sad and distressing news of the assassination of my brother and colleague, Hon. Olatoye Temitope Sugar, in Oyo State today. The murder of Hon Sugar in election violence today is primitive, wicked, inhumane, barbaric and highly condemnable'.


Comments