Àwon Adigunjalè kolu ilé ìfowópamó kan ní ìpínlè Ekiti


 Ojo buruku esu gbomimu lo je nigba ti awon adigunjale mefa kan kolu ile ifowopamo si kan to wa ni agbegbe Irepodun/Ifelodun ni ilu Iyin Ekiti. Gege bi atejade ti awon ti oro na se oju won se, won fi han wipe opopolopo awon oun ija oloro ni awon adigun jale na ko wa lati wa fi sose ninu ilu na, ti won si ko opolopo owo ati dukia lo.

Won so siwaju si wipe nise ni awon agbofinro fese fe nigba ti won gbo iro ibon, eleyi lo fa ti awon adigunjale na fi se aseyori ninu ise ijamba ti won wa se.

Agbenuso fun awon olopa nigba ti oun ba awon onirohin soro bakana fi idi oro na mule, o si ro awon omo ilu na lati fokan bale, wipe lai pe, owo awon won o ba awon odaran na.

Comments